"Òkìkí." - Brymo
Arìn ìrìn àjò mi ò m'aìdélé
Mo wọ̀lú, mo yà bàrà délé onínnkan
Ló bá ní n fobọ́, kí n tó wẹwọ, kí n tó jẹ iyán
Wọ́n ní n bẹṣu, kí 'n tó yọfe, kí n tó m'ògùrọ̀
Balógun ló fẹ́ ṣoṣó dẹrú kó má ràn
Ó ló ju t'òhun lọ, kò ma rán
Ta ni baba tó bí mi l'ọmọ?
Ibo mo ti ṣè wá? Wà n ruga s'awọn
Àmọ́ o ràn (O ràn)
O ràn (O ràn)
O ràn, òkìkí mí ràn
O ràn (O ràn)
O ràn (O ràn)
O ràn, òkìkí mí ràn
Mo ronú títí, mo gbọ́rọ̀ tì, n ò lè paátì
Ẹni abíire ni mí, n ò lè fòdodo ṣawátì
Nṣe ni mo bò s'ọ̀nà, mo wọ sálubàtà, mo gẹ fìlà
Nṣe ni mo bò s'ọ̀nà, n ò rìn fìà-fìà, n ò ṣẹ fàlà-fàlà
Balógun ló fẹ́ ṣoṣó dẹrú kó má ràn
Ó ló ju t'òun lọ, kò ma rán
Ta ni baba tó bí mi l'ọmọ?
Ibo mo ti ṣè wá? Wà n ruga s'awọn
Àmọ́ o ràn (O ràn)
O ràn (O ràn)
O ràn, òkìkí mí ràn
O ràn (O ràn)
O ràn (O ràn)
O ràn, òkìkí mí ràn
Balógun ló fẹ́ p'òkòkí ẹlòmíràn
Ó ló ju t'òun lọ, kò ma rán
Pe ta ni baba tó bí mi l'ọmọ?
Ọ̀gbẹ̀rì lawo níwájú òrìṣà kò mọ
Àmọ́ o ràn
O ràn, o ràn
N ò fẹ́ òkìkí òmíràn
O ràn
O ràn
O ràn, òkìkí mí ràn
Writer(s): Ọláwálé Ọlọ́fọ̀’rọ̀.
All lyrical content displayed on this website is the intellectual property of its respective copyright holders. No ownership is implied, and no copyright infringement is intended.
Subscribe now and never miss a new song lyric update.
Òkìkí